Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 116:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI fẹ Oluwa nitori ti o gbọ́ ohùn mi ati ẹ̀bẹ mi.

2. Nitori ti o dẹ eti rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ma kepè e niwọn ọjọ mi.

3. Ikẹkùn ikú yi mi ka, ati irora isà-òkú di mi mu; mo ri iyọnu ati ikãnu.

4. Nigbana ni mo kepè orukọ Oluwa; Oluwa, emi bẹ̀ ọ, gbà ọkàn mi.

5. Olore-ọfẹ li Oluwa, ati olododo; nitõtọ, alãnu li Ọlọrun wa.

6. Oluwa pa awọn alaimọ̀kan mọ́: a rẹ̀ mi silẹ tan, o si ràn mi lọwọ.

7. Pada si ibi isimi rẹ, iwọ ọkàn mi; nitori ti Oluwa ṣe é lọ́pọlọpọ fun ọ.

8. Nitori ti iwọ gbà ọkàn mi lọwọ ikú, oju mi lọwọ omije, ati ẹsẹ mi lọwọ iṣubu.

9. Emi o ma rìn niwaju Oluwa ni ilẹ alãye.

10. Emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: mo ri ipọnju gidigidi.

Ka pipe ipin O. Daf 116