Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 113:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ ma yìn Oluwa! Ẹ ma yìn, ẹnyin iranṣẹ Oluwa, ẹ ma yìn orukọ Oluwa.

2. Ibukún li orukọ Oluwa lati isisiyi lọ ati si i lailai.

3. Lati ila-õrun titi o fi de ìwọ rẹ̀ orukọ Oluwa ni ki a yìn.

4. Oluwa ga lori gbogbo orilẹ-ède, ogo rẹ̀ si wà lori ọrun.

5. Tali o dabi Oluwa Ọlọrun wa, ti o ngbe ibi giga.

6. Ẹniti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ lati wò ohun ti o wà li ọrun ati li aiye!

7. O gbé talaka soke lati inu erupẹ wá, o si gbé olupọnju soke lati ori àtan wá;

8. Ki o le mu u joko pẹlu awọn ọmọ-alade, ani pẹlu awọn ọmọ-alade awọn enia rẹ̀.

9. O mu àgan obinrin gbe inu ile, lati ma ṣe oninu-didùn iya awọn ọmọ. Ẹ ma yìn Oluwa!

Ka pipe ipin O. Daf 113