Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 108:6-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là: fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si da mi lohùn.

7. Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu.

8. Ti emi ni Gileadi: ti emi ni Manasse: Efraimu pẹlu li agbara ori mi: Juda li olofin mi:

9. Moabu ni ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bata mi si; lori Filistia li emi o ho iho-ayọ̀.

10. Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi ni? tani yio sìn mi lọ si Edomu?

11. Iwọ Ọlọrun ha kọ́, ẹniti o ti ṣa wa tì? Ọlọrun, iwọ kì yio si ba awọn ogun wa jade lọ?

12. Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori asan ni iranlọwọ enia.

13. Nipasẹ Ọlọrun li awa o ṣe akin; nitori on ni yio tẹ̀ awọn ọta wa mọlẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 108