Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 108:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLỌRUN, ọkàn mi ti mura, emi o ma kọrin, emi o si ma fi ogo mi kọrin iyìn.

2. Ji, ohun-elo orin mimọ́ ati dùrù: emi tikarami yio si ji ni kutukutu.

3. Emi o ma yìn ọ, Oluwa, ninu awọn enia: emi o mã kọrin si ọ ninu awọn orilẹ-ède.

4. Nitori ti ãnu rẹ tobi jù ọrun lọ: ati otitọ rẹ titi de awọsanma.

5. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, lori awọn ọrun: ati ogo rẹ lori gbogbo aiye.

6. Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là: fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si da mi lohùn.

7. Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu.

8. Ti emi ni Gileadi: ti emi ni Manasse: Efraimu pẹlu li agbara ori mi: Juda li olofin mi:

9. Moabu ni ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bata mi si; lori Filistia li emi o ho iho-ayọ̀.

10. Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi ni? tani yio sìn mi lọ si Edomu?

11. Iwọ Ọlọrun ha kọ́, ẹniti o ti ṣa wa tì? Ọlọrun, iwọ kì yio si ba awọn ogun wa jade lọ?

12. Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori asan ni iranlọwọ enia.

Ka pipe ipin O. Daf 108