Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 106:36-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Nwọn si sìn ere wọn: ti o di ikẹkun fun wọn.

37. Nitõtọ nwọn fi ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn rubọ si oriṣa.

38. Nwọn si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ, ani ẹ̀jẹ awọn ọmọkunrin wọn ati ti awọn ọmọbinrin wọn, ti nwọn fi rubọ si ere Kenaani: ilẹ na si di aimọ́ fun ẹ̀jẹ.

39. Nwọn si fi iṣẹ ara wọn sọ ara wọn di alaimọ́, nwọn si ṣe panṣaga lọ pẹlu iṣẹ wọn.

40. Nitorina ni ibinu Oluwa ṣe ràn si awọn enia rẹ̀, o si korira awọn enia ini rẹ̀.

41. O si fi wọn le awọn keferi lọwọ; awọn ti o korira wọn si ṣe olori wọn.

42. Awọn ọta wọn si ni wọn lara, nwọn si mu wọn sìn labẹ ọwọ wọn.

43. Igba pupọ li o gbà wọn; sibẹ nwọn fi ìmọ wọn mu u binu, a si rẹ̀ wọn silẹ nitori ẹ̀ṣẹ wọn.

44. Ṣugbọn ninu ipọnju o kiyesi wọn, nigbati o gbọ́ ẹkún wọn.

Ka pipe ipin O. Daf 106