Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 106:24-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Nitõtọ, nwọn kò kà ilẹ didara nì si, nwọn kò gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́:

25. Ṣugbọn nwọn nkùn ninu agọ wọn, nwọn kò si feti si ohùn Oluwa.

26. Nitorina li o ṣe gbé ọwọ rẹ̀ soke si wọn, lati bì wọn ṣubu li aginju:

27. Lati bì iru-ọmọ wọn ṣubu pẹlu lãrin awọn orilẹ-ède, ati lati fún wọn ka kiri ni ilẹ wọnni.

28. Nwọn da ara wọn pọ̀ pẹlu mọ Baali-Peoru, nwọn si njẹ ẹbọ okú.

29. Bayi ni nwọn fi iṣẹ wọn mu u binu: àrun nla si fó si arin wọn.

30. Nigbana ni Finehasi dide duro, o si ṣe idajọ: bẹ̃li àrun nla na si dá.

31. A si kà eyi na si fun u li ododo lati irandiran titi lai.

32. Nwọn bi i ninu pẹlu nibi omi Ijà, bẹ̃li o buru fun Mose nitori wọn:

33. Nitori ti nwọn mu ẹmi rẹ̀ binu, bẹ̃li o fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ aiyẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 106