Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 106:14-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nwọn si ṣe ifẹkufẹ li aginju, nwọn si dan Ọlọrun wò ninu aṣálẹ̀.

15. O si fi ifẹ wọn fun wọn; ṣugbọn o rán rirù si ọkàn wọn.

16. Nwọn ṣe ilara Mose pẹlu ni ibudo, ati Aaroni, ẹni-mimọ́ Oluwa.

17. Ilẹ là, o si gbé Datani mì, o si bò ẹgbẹ́ Abiramu mọlẹ.

18. Iná si ràn li ẹgbẹ́ wọn; ọwọ́ iná na jó awọn enia buburu.

19. Nwọn ṣe ẹgbọrọ malu ni Horebu, nwọn si foribalẹ fun ere didà.

20. Bayi ni nwọn pa ogo wọn dà si àworan malu ti njẹ koriko.

21. Nwọn gbagbe Ọlọrun, Olugbala wọn, ti o ti ṣe ohun nla ni ilẹ Egipti.

22. Iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu, ati ohun ẹ̀ru lẹba Okun pupa.

23. Nitorina li o ṣe wipe, on o run wọn, iba máṣe pe Mose, ayanfẹ rẹ̀, duro niwaju rẹ̀ li oju-ẹya na, lati yi ibinu rẹ̀ pada, ki o má ba run wọn.

24. Nitõtọ, nwọn kò kà ilẹ didara nì si, nwọn kò gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́:

25. Ṣugbọn nwọn nkùn ninu agọ wọn, nwọn kò si feti si ohùn Oluwa.

Ka pipe ipin O. Daf 106