Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 105:28-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. O rán òkunkun, o si mu u ṣú; nwọn kò si ṣaigbọran si ọ̀rọ rẹ̀.

29. O sọ omi wọn di ẹ̀jẹ, o si pa ẹja wọn.

30. Ilẹ wọn mu ọ̀pọlọ jade wá li ọ̀pọlọpọ, ni iyẹwu awọn ọba wọn.

31. O sọ̀rọ, oniruru eṣinṣin si de, ati ina-aṣọ ni gbogbo agbegbe wọn.

Ka pipe ipin O. Daf 105