Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 104:15-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ati ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati oróro ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le.

16. Igi Oluwa kún fun oje, igi kedari Lebanoni, ti o ti gbìn.

17. Nibiti awọn ẹiyẹ ntẹ́ itẹ́ wọn: bi o ṣe ti àkọ ni, igi firi ni ile rẹ̀.

18. Awọn òke giga li àbo fun awọn ewurẹ igbẹ: ati awọn apata fun awọn ehoro.

19. O da oṣupa fun akokò: õrùn mọ̀ akokò ìwọ rẹ̀.

20. Iwọ ṣe òkunkun, o si di oru: ninu eyiti gbogbo ẹranko igbo nrìn kiri.

21. Awọn ẹgbọrọ kiniun ndún si ohun ọdẹ wọn, nwọn si nwá onjẹ wọn lọwọ Ọlọrun.

22. Õrùn là, nwọn kó ara wọn jọ, nwọn dubulẹ ninu iho wọn.

23. Enia jade lọ si iṣẹ rẹ̀ ati si lãla rẹ̀ titi di aṣalẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 104