Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 104:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. O mbomi rin awọn òke lati iyẹwu rẹ̀ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ tẹ́ aiye lọrun.

14. O mu koriko dagba fun ẹran, ati ewebẹ fun ìlo enia: ki o le ma mu onjẹ jade lati ilẹ wá;

15. Ati ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati oróro ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le.

16. Igi Oluwa kún fun oje, igi kedari Lebanoni, ti o ti gbìn.

17. Nibiti awọn ẹiyẹ ntẹ́ itẹ́ wọn: bi o ṣe ti àkọ ni, igi firi ni ile rẹ̀.

18. Awọn òke giga li àbo fun awọn ewurẹ igbẹ: ati awọn apata fun awọn ehoro.

19. O da oṣupa fun akokò: õrùn mọ̀ akokò ìwọ rẹ̀.

20. Iwọ ṣe òkunkun, o si di oru: ninu eyiti gbogbo ẹranko igbo nrìn kiri.

Ka pipe ipin O. Daf 104