Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 104:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Oluwa, Ọlọrun mi, iwọ tobi jọjọ: ọlá ati ọla-nla ni iwọ wọ̀ li aṣọ.

2. Ẹniti o fi imọlẹ bora bi aṣọ: ẹniti o ta ọrun bi aṣọ tita:

3. Ẹniti o fi omi ṣe ìti igi-àja iyẹwu rẹ̀: ẹniti o ṣe awọsanma ni kẹkẹ́ rẹ̀, ẹniti o nrìn lori apa iyẹ afẹfẹ:

4. Ẹniti o ṣe ẹfufu ni onṣẹ rẹ̀; ati ọwọ-iná ni iranṣẹ rẹ̀.

5. Ẹniti o fi aiye sọlẹ lori ipilẹ rẹ̀, ti kò le ṣipò pada lailai.

6. Iwọ fi ibu omi bò o mọlẹ bi aṣọ: awọn omi duro lori òke nla.

7. Nipa ibawi rẹ nwọn sá; nipa ohùn ãra rẹ, nwọn yara lọ.

8. Awọn òke nla nru soke; awọn afonifoji nsọkalẹ si ibi ti iwọ ti fi lelẹ fun wọn.

9. Iwọ ti pa àla kan ki nwọn ki o má le kọja rẹ̀; ki nwọn ki o má tun pada lati bò aiye mọlẹ.

10. Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke.

11. Awọn ni nfi omi mimu fun gbogbo ẹranko igbẹ: awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ npa ongbẹ wọn;

12. Lẹba wọn li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio ni ile wọn, ti nkọrin lãrin ẹka igi.

Ka pipe ipin O. Daf 104