Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 103:7-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O fi ọ̀na rẹ̀ hàn fun Mose, iṣe rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli.

8. Oluwa li alãnu ati olõre, o lọra ati binu, o si pọ̀ li ãnu.

9. On kì ibaniwi nigbagbogbo: bẹ̃ni kì ipa ibinu rẹ̀ mọ́ lailai.

10. On kì iṣe si wa gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ wa; bẹ̃ni kì isan a fun wa gẹgẹ bi aiṣedede wa.

11. Nitori pe, bi ọrun ti ga si ilẹ, bẹ̃li ãnu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.

12. Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa.

13. Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.

14. Nitori ti o mọ̀ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa.

15. Bi o ṣe ti enia ni, ọjọ rẹ̀ dabi koriko: bi itana eweko igbẹ bẹ̃li o gbilẹ.

16. Nitori ti afẹfẹ fẹ kọja lọ lori rẹ̀, kò sì si mọ́; ibujoko rẹ̀ kò mọ̀ ọ mọ́.

17. Ṣugbọn ãnu Oluwa lati aiyeraiye ni lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ododo rẹ̀ lati ọmọ de ọmọ:

18. Si awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ mọ́, ati si awọn ti o ranti ofin rẹ̀ lati ṣe wọn.

19. Oluwa ti pèse itẹ́ rẹ̀ ninu ọrun; ijọba rẹ̀ li o si bori ohun gbogbo;

20. Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin angeli rẹ̀, ti o pọ̀ ni ipa ti nṣe ofin rẹ̀, ti nfi eti si ohùn ọ̀rọ rẹ̀.

21. Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀ gbogbo; ẹnyin iranṣẹ rẹ̀, ti nṣe ifẹ rẹ̀.

22. Ẹ fi ibukún fun Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ̀ ni ibi gbogbo ijọba rẹ̀: fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi.

Ka pipe ipin O. Daf 103