Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 103:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, ati gbogbo ohun ti o wà ninu mi, fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́.

2. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rẹ̀:

3. Ẹniti o dari gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ jì; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ,

4. Ẹniti o ra ẹmi rẹ kuro ninu iparun; ẹniti o fi iṣeun-ifẹ ati iyọ́nu de ọ li ade:

5. Ẹniti o fi ohun didara tẹ́ ọ lọrun: bẹ̃ni igba ewe rẹ di ọtun bi ti idì.

6. Oluwa ṣe ododo ati idajọ fun gbogbo awọn ti a nilara.

7. O fi ọ̀na rẹ̀ hàn fun Mose, iṣe rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli.

Ka pipe ipin O. Daf 103