Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 102:20-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Lati gbọ́ irora ara-tubu; lati tú awọn ti a yàn si ikú silẹ;

21. Lati sọ orukọ Oluwa ni Sioni, ati iyìn rẹ̀ ni Jerusalemu.

22. Nigbati a kó awọn enia jọ pọ̀ ati awọn ijọba, lati ma sìn Oluwa.

23. O rẹ̀ agbara mi silẹ li ọ̀na; o mu ọjọ mi kuru.

24. Emi si wipe, Ọlọrun mi, máṣe mu mi kuro li agbedemeji ọjọ mi: lati irandiran li ọdun rẹ.

25. Lati igba atijọ ni iwọ ti fi ipilẹ aiye sọlẹ: ọrun si ni iṣẹ ọwọ rẹ,

26. Nwọn o ṣegbe, ṣugbọn Iwọ o duro; nitõtọ gbogbo wọn ni yio di ogbó bi aṣọ; bi ẹ̀wu ni iwọ o pàrọ wọn, nwọn o si pàrọ.

27. Ṣugbọn bakanna ni Iwọ, ọdun rẹ kò li opin.

28. Awọn ọmọ awọn iranṣẹ rẹ yio duro pẹ, a o si fi ẹsẹ iru-ọmọ wọn mulẹ niwaju rẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 102