Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 102:13-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Iwọ o dide, iwọ o ṣãnu fun Sioni: nitori igba ati ṣe oju-rere si i, nitõtọ, àkoko na de.

14. Nitori ti awọn iranṣẹ rẹ ṣe inu didùn si okuta rẹ̀, nwọn si kãnu erupẹ rẹ̀.

15. Bẹ̃li awọn keferi yio ma bẹ̀ru orukọ Oluwa, ati gbogbo ọba aiye yio ma bẹ̀ru ogo rẹ.

16. Nigbati Oluwa yio gbé Sioni ró, yio farahan ninu ogo rẹ̀.

17. Yio juba adura awọn alaini, kì yio si gàn adura wọn.

18. Eyi li a o kọ fun iran ti mbọ̀; ati awọn enia ti a o da yio ma yìn Oluwa.

19. Nitori ti o wò ilẹ lati òke ibi-mimọ́ rẹ̀ wá; lati ọrun wá ni Oluwa bojuwo aiye;

20. Lati gbọ́ irora ara-tubu; lati tú awọn ti a yàn si ikú silẹ;

21. Lati sọ orukọ Oluwa ni Sioni, ati iyìn rẹ̀ ni Jerusalemu.

Ka pipe ipin O. Daf 102