Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 102:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. GBỌ adura mi, Oluwa, ki o si jẹ ki igbe mi ki o wá sọdọ rẹ.

2. Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi li ọjọ ti emi wà ninu ipọnju; dẹ eti rẹ si mi: li ọjọ ti mo ba pè, da mi lohùn-lọgan.

3. Nitori ti ọjọ mi run bi ẹ̃fin, egungun mi si jona bi àro.

4. Aiya mi lù, o si rọ bi koriko; tobẹ̃ ti mo gbagbe lati jẹ onjẹ mi.

5. Nitori ohùn ikerora mi, egungun mi lẹ̀ mọ ẹran-ara mi.

6. Emi dabi ẹiyẹ ofú ni iju: emi dabi owiwi ibi ahoro.

7. Emi nṣọra, emi dabi ologoṣẹ nikan ni ori ile.

8. Awọn ọta mi ngàn mi li ọjọ gbogbo; ati awọn ti nṣe ikanra si mi, nwọn fi mi bu.

9. Emi sa jẹ ẽru bi onjẹ, emi si dà ohun mimu mi pọ̀ pẹlu omije.

10. Nitori ikannu ati ibinu rẹ; nitori iwọ ti gbé mi soke, iwọ si gbé mi ṣanlẹ.

11. Ọjọ mi dabi ojiji ti o nfà sẹhin; emi si nrọ bi koriko.

12. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ni yio duro lailai; ati iranti rẹ lati iran dé iran.

13. Iwọ o dide, iwọ o ṣãnu fun Sioni: nitori igba ati ṣe oju-rere si i, nitõtọ, àkoko na de.

Ka pipe ipin O. Daf 102