Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 100:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, ẹnyin ilẹ gbogbo.

2. Ẹ fi ayọ̀ sìn Oluwa: ẹ wá ti ẹnyin ti orin si iwaju rẹ̀.

3. Ki ẹnyin ki o mọ̀ pe Oluwa, on li Ọlọrun: on li o dá wa, tirẹ̀ li awa; awa li enia rẹ̀, ati agutan papa rẹ̀.

4. Ẹ lọ si ẹnu ọ̀na rẹ̀ ti ẹnyin ti ọpẹ, ati si agbala rẹ̀ ti ẹnyin ti iyìn: ẹ ma dupẹ fun u, ki ẹ si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀.

5. Nitori ti Oluwa pọ̀ li ore; ãnu rẹ̀ kò nipẹkun; ati otitọ rẹ̀ lati iran-diran.

Ka pipe ipin O. Daf 100