Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 10:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EṢE ti iwọ fi duro li òkere rere, Oluwa; ẽṣe ti iwọ fi fi ara pamọ́ ni igba ipọnju.

2. Ninu igberaga li enia buburu nṣe inunibini si awọn talaka: ninu arekereke ti nwọn rò ni ki a ti mu wọn.

3. Nitori enia buburu nṣogo ifẹ ọkàn rẹ̀, o si nsure fun olojukokoro, o si nkẹgan Oluwa.

4. Enia buburu, nipa igberaga oju rẹ̀, kò fẹ ṣe afẹri Ọlọrun: Ọlọrun kò si ni gbogbo ironu rẹ̀.

5. Ọ̀na rẹ̀ nlọ siwaju nigbagbogbo; idajọ rẹ jina rere kuro li oju rẹ̀; gbogbo awọn ọta rẹ̀ li o nfẹ̀ si.

6. O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, A kì yio ṣi mi ni ipò: lati irandiran emi kì yio si ninu ipọnju.

7. Ẹnu rẹ̀ kún fun egún, ati fun ẹ̀tan, ati fun itanjẹ: ìwa-ìka ati ìwa-asan mbẹ labẹ ahọn rẹ̀.

8. O joko ni buba ni ileto wọnni: ni ibi ìkọkọ wọnni li o npa awọn alaiṣẹ̀: oju rẹ̀ nṣọ́ awọn talaka nikọkọ.

9. O lùmọ ni ibi ìkọkọ bi kiniun ninu pantiri: o lùmọ lati mu talaka: a si mu talaka, nigbati o ba fà a sinu àwọn rẹ̀.

10. O ba, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ki talaka ki o le bọ́ si ọwọ agbara rẹ̀.

11. O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun ti gbagbe: o pa oju rẹ̀ mọ́; on kì yio ri i lailai.

12. Dide, Oluwa; Ọlọrun, gbé ọwọ rẹ soke: máṣe gbagbe olupọnju.

Ka pipe ipin O. Daf 10