Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 9:18-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Nipa aṣẹ OLUWA awọn ọmọ Israeli a ṣí, nipa aṣẹ OLUWA nwọn a si dó: ni gbogbo ọjọ́ ti awọsanma ba simi lori agọ́ na, nwọn a dó.

19. Nigbati awọsanma ba si pẹ li ọjọ́ pupọ̀ lori agọ́ na, awọn ọmọ Israeli a si ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, nwọn ki si iṣi.

20. Nigba miran awọsanma a wà li ọjọ́ diẹ lori agọ́ na; nigbana gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a dó, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a si ṣí.

21. Nigba miran awọsanma a duro lati alẹ titi di owurọ̀; nigbati awọsanma si ṣí soke li owurọ̀, nwọn a ṣí: iba ṣe li ọsán tabi li oru, ti awọsanma ba ká soke, nwọn a ṣí.

22. Bi ijọ́ meji ni, tabi oṣù kan, tabi ọdún kan, ti awọsanma ba pẹ lori agọ́ na, ti o simi lé e, awọn ọmọ Israeli a dó, nwọn ki si iṣí: ṣugbọn nigbati o ba ká soke, nwọn a ṣí.

23. Nipa aṣẹ OLUWA nwọn a dó, ati nipa aṣẹ OLUWA nwọn a ṣí: nwọn a ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.

Ka pipe ipin Num 9