Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 9:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, li oṣù kini ọdún keji ti nwọn ti ilẹ Egipti jade wá, wipe,

2. Ki awọn ọmọ Israeli ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ li akokò rẹ̀.

3. Li ọjọ́ kẹrinla oṣù yi, li aṣalẹ, ni ki ẹnyin ki o ma ṣe e li akokò rẹ̀: gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀ gbogbo, ati gẹgẹ bi ìlana rẹ̀ gbogbo, ni ki ẹnyin ki o pa a mọ́.

4. Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o ma pa ajọ irekọja mọ́:

5. Nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla, oṣù kini, li aṣalẹ ni ijù Sinai: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe.

6. Awọn ọkunrin kan wà ti nwọn ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́, nwọn kò si le ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ na: nwọn si wá siwaju Mose ati siwaju Aaroni li ọjọ́ na:

Ka pipe ipin Num 9