Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 5:1-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o yọ gbogbo adẹ̀tẹ kuro ni ibudó, ati gbogbo ẹniti o ní isun, ati ẹnikẹni ti o di alaimọ́ nipa okú:

3. Ati ọkunrin ati obinrin ni ki ẹnyin ki o yọ kuro, lẹhin ode ibudó ni ki ẹ fi wọn si; ki nwọn ki o máṣe sọ ibudó wọn di alaimọ́, lãrin eyiti Emi ngbé.

4. Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃, nwọn si yọ wọn sẹhin ibudó: bi OLUWA ti sọ fun Mose, bẹ̃ li awọn ọmọ Israeli ṣe.

5. OLUWA si sọ fun Mose pe,

6. Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba dá ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ti enia ida, ti o ṣe irekọja si OLUWA, ti oluwarẹ̀ si jẹ̀bi;

7. Nigbana ni ki nwọn ki o jẹwọ ẹ̀ṣẹ ti nwọn ṣẹ̀: ki o si san ẹsan ẹ̀ṣẹ rẹ̀ li oju-owo, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun ẹniti on jẹbi rẹ̀.

8. Bi o ba si ṣepe ọkunrin na kò ní ibatan kan lati san ẹsan ẹ̀ṣẹ na fun, ki a san ẹsan na fun OLUWA, ani fun alufa; pẹlu àgbo ètutu, ti a o fi ṣètutu fun u.

9. Ati gbogbo ẹbọ agbesọsoke ohun mimọ́ gbogbo ti awọn ọmọ Israeli, ti nwọn mú tọ̀ alufa wá, yio jẹ́ tirẹ̀.

10. Ati ohun mimọ́ olukuluku, ki o jẹ́ tirẹ̀: ohunkohun ti ẹnikan ba fi fun alufa ki o jẹ́ tirẹ̀.

11. OLUWA si sọ fun Mose pe,

12. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Bi aya ọkunrin kan ba yapa, ti o si ṣẹ̀ ẹ,

13. Ti ọkunrin kan si bá a dàpọ, ti o si pamọ́ fun ọkọ rẹ̀, ti o si sin, ti on si di ẹni ibàjẹ́, ti kò si sí ẹlẹri kan si i, ti a kò si mú u mọ ọ,

14. Ti ẹmi owú ba dé si i, ti o si njowú aya rẹ̀, ti obinrin na si di ẹni ibàjẹ́: tabi bi ẹmi owú ba dé si i, ti o si njowú aya rẹ̀, ṣugbọn ti on kò di ẹni ibàjẹ́:

15. Nigbana ni ki ọkunrin na ki o mú aya rẹ́ tọ̀ alufa wá, ki o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun u, idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun barle; ki o máṣe dà oróro sori rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sinu rẹ̀; nitoripe ẹbọ ohunjijẹ owú ni, ẹbọ ohunjijẹ iranti ni, ti nmú irekọja wá si iranti.

16. Ki alufa na ki o si mú u sunmọtosi, ki o mu u duro niwaju OLUWA:

Ka pipe ipin Num 5