Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 35:8-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ati ilu ti ẹnyin o fi fun wọn, ki o jẹ́ ninu ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli, lọwọ ẹniti o ní pupọ̀ lí ẹnyin o gbà pupọ̀; ṣugbọn lọwọ ẹniti o ní diẹ li ẹnyin o gbà diẹ: ki olukuluku ki o fi ninu ilu rẹ̀ fun awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ilẹ-iní rẹ̀ ti o ní.

9. OLUWA si sọ fun Mose pe,

10. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ Kenaani;

11. Nigbana ni ki ẹnyin ki o yàn ilu fun ara nyin ti yio jẹ́ ilu àbo fun nyin; ki apania ti o pa enia li aimọ̀ ki o le ma sa lọ sibẹ̀.

12. Nwọn o si jasi ilu àbo kuro lọwọ agbẹsan; ki ẹniti o pa enia ki o má ba kú titi yio fi duro niwaju ijọ awọn enia ni idajọ.

13. Ati ninu ilu wọnyi ti ẹnyin o fi fun wọn, mẹfa yio jẹ́ ilu àbo fun nyin.

14. Ki ẹnyin ki o yàn ilu mẹta ni ìha ihin Jordani, ki ẹnyin ki o si yàn ilu mẹta ni ilẹ Kenaani, ti yio ma jẹ́ ilu àbo.

15. Ilu mẹfa wọnyi ni yio ma jẹ́ àbo fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ati fun atipo lãrin wọn: ki olukuluku ẹniti o ba pa enia li aimọ̀ ki o le ma salọ sibẹ̀.

16. Ṣugbọn bi o ba fi ohunèlo irin lù u, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na.

17. Ati bi o ba sọ okuta lù u, ti o le ti ipa rẹ̀ kú, ti o si kú, apania li on: a o pa apania na.

18. Tabi bi o ba fi ohun-èlo igi lù u, ti o le ti ipa rẹ̀ kú, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na.

19. Agbẹsan ẹ̀jẹ tikalarẹ̀ ni ki o pa apania na: nigbati o ba bá a, ki o pa a.

Ka pipe ipin Num 35