Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 35:5-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ki ẹnyin ki o si wọ̀n lati ẹhin ode ilu na lọ ni ìha ìla-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha gusù ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ariwa ẹgba igbọnwọ; ki ilu na ki o si wà lãrin. Eyi ni yio si ma ṣe ẹbẹba-ilu fun wọn.

6. Ati ninu ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, mẹfa o jẹ́ ilu àbo, ti ẹnyin o yàn fun aṣi-enia-pa, ki o le ma salọ sibẹ̀: ki ẹnyin ki o si fi ilu mejilelogoji kún wọn.

7. Gbogbo ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi ki o jẹ́ mejidilãdọta: wọnyi ni ki ẹnyin fi fun wọn pẹlu ẹbẹba wọn.

8. Ati ilu ti ẹnyin o fi fun wọn, ki o jẹ́ ninu ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli, lọwọ ẹniti o ní pupọ̀ lí ẹnyin o gbà pupọ̀; ṣugbọn lọwọ ẹniti o ní diẹ li ẹnyin o gbà diẹ: ki olukuluku ki o fi ninu ilu rẹ̀ fun awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ilẹ-iní rẹ̀ ti o ní.

9. OLUWA si sọ fun Mose pe,

10. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ Kenaani;

11. Nigbana ni ki ẹnyin ki o yàn ilu fun ara nyin ti yio jẹ́ ilu àbo fun nyin; ki apania ti o pa enia li aimọ̀ ki o le ma sa lọ sibẹ̀.

12. Nwọn o si jasi ilu àbo kuro lọwọ agbẹsan; ki ẹniti o pa enia ki o má ba kú titi yio fi duro niwaju ijọ awọn enia ni idajọ.

13. Ati ninu ilu wọnyi ti ẹnyin o fi fun wọn, mẹfa yio jẹ́ ilu àbo fun nyin.

14. Ki ẹnyin ki o yàn ilu mẹta ni ìha ihin Jordani, ki ẹnyin ki o si yàn ilu mẹta ni ilẹ Kenaani, ti yio ma jẹ́ ilu àbo.

15. Ilu mẹfa wọnyi ni yio ma jẹ́ àbo fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ati fun atipo lãrin wọn: ki olukuluku ẹniti o ba pa enia li aimọ̀ ki o le ma salọ sibẹ̀.

16. Ṣugbọn bi o ba fi ohunèlo irin lù u, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na.

Ka pipe ipin Num 35