4. Ati ẹbẹba-ilu, ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, lati odi ilu lọ sẹhin rẹ̀ ki o jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ yiká.
5. Ki ẹnyin ki o si wọ̀n lati ẹhin ode ilu na lọ ni ìha ìla-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha gusù ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ariwa ẹgba igbọnwọ; ki ilu na ki o si wà lãrin. Eyi ni yio si ma ṣe ẹbẹba-ilu fun wọn.
6. Ati ninu ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, mẹfa o jẹ́ ilu àbo, ti ẹnyin o yàn fun aṣi-enia-pa, ki o le ma salọ sibẹ̀: ki ẹnyin ki o si fi ilu mejilelogoji kún wọn.
7. Gbogbo ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi ki o jẹ́ mejidilãdọta: wọnyi ni ki ẹnyin fi fun wọn pẹlu ẹbẹba wọn.
8. Ati ilu ti ẹnyin o fi fun wọn, ki o jẹ́ ninu ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli, lọwọ ẹniti o ní pupọ̀ lí ẹnyin o gbà pupọ̀; ṣugbọn lọwọ ẹniti o ní diẹ li ẹnyin o gbà diẹ: ki olukuluku ki o fi ninu ilu rẹ̀ fun awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ilẹ-iní rẹ̀ ti o ní.
9. OLUWA si sọ fun Mose pe,
10. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ Kenaani;
11. Nigbana ni ki ẹnyin ki o yàn ilu fun ara nyin ti yio jẹ́ ilu àbo fun nyin; ki apania ti o pa enia li aimọ̀ ki o le ma sa lọ sibẹ̀.
12. Nwọn o si jasi ilu àbo kuro lọwọ agbẹsan; ki ẹniti o pa enia ki o má ba kú titi yio fi duro niwaju ijọ awọn enia ni idajọ.
13. Ati ninu ilu wọnyi ti ẹnyin o fi fun wọn, mẹfa yio jẹ́ ilu àbo fun nyin.
14. Ki ẹnyin ki o yàn ilu mẹta ni ìha ihin Jordani, ki ẹnyin ki o si yàn ilu mẹta ni ilẹ Kenaani, ti yio ma jẹ́ ilu àbo.