Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 35:26-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Ṣugbọn bi apania na ba ṣèṣi jade lọ si opinlẹ ilu àbo rẹ̀, nibiti o ti sá si;

27. Ti agbẹsan ẹ̀jẹ na si ri i lẹhin opinlẹ ilu àbo rẹ̀, ti agbẹsan ẹ̀jẹ si pa apania na; on ki yio jẹbi ẹ̀jẹ:

28. Nitoripe on iba joko ninu ilu àbo rẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa: ati lẹhin ikú olori alufa ki apania na ki o pada lọ si ilẹ iní rẹ̀.

29. Ohun wọnyi ni o si jẹ́ ìlana idajọ fun nyin ni iraniran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.

30. Ẹnikẹni ti o ba pa enia, lati ẹnu awọn ẹlẹri wá li a o pa apania na: ṣugbọn ẹlẹri kanṣoṣo ki yio jẹri si ẹnikan lati pa a.

31. Pẹlupẹlu ki ẹnyin ki o máṣe gbà ohun-irasilẹ fun ẹmi apania, ti o jẹbi ikú: ṣugbọn pipa ni ki a pa a.

Ka pipe ipin Num 35