Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 35:12-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nwọn o si jasi ilu àbo kuro lọwọ agbẹsan; ki ẹniti o pa enia ki o má ba kú titi yio fi duro niwaju ijọ awọn enia ni idajọ.

13. Ati ninu ilu wọnyi ti ẹnyin o fi fun wọn, mẹfa yio jẹ́ ilu àbo fun nyin.

14. Ki ẹnyin ki o yàn ilu mẹta ni ìha ihin Jordani, ki ẹnyin ki o si yàn ilu mẹta ni ilẹ Kenaani, ti yio ma jẹ́ ilu àbo.

15. Ilu mẹfa wọnyi ni yio ma jẹ́ àbo fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ati fun atipo lãrin wọn: ki olukuluku ẹniti o ba pa enia li aimọ̀ ki o le ma salọ sibẹ̀.

16. Ṣugbọn bi o ba fi ohunèlo irin lù u, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na.

17. Ati bi o ba sọ okuta lù u, ti o le ti ipa rẹ̀ kú, ti o si kú, apania li on: a o pa apania na.

18. Tabi bi o ba fi ohun-èlo igi lù u, ti o le ti ipa rẹ̀ kú, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na.

19. Agbẹsan ẹ̀jẹ tikalarẹ̀ ni ki o pa apania na: nigbati o ba bá a, ki o pa a.

20. Ṣugbọn bi o ba ṣepe o fi irira gún u, tabi ti o ba sọ nkan lù u, lati ibuba wá, ti on si kú;

21. Tabi bi o nṣe ọtá, ti o fi ọwọ́ rẹ̀ lù u, ti on si kú: ẹniti o lù u nì pipa li a o pa a; nitoripe apania li on: agbẹsan ẹ̀jẹ ni ki o pa apania na, nigbati o ba bá a.

22. Ṣugbọn bi o ba fi nkan gún u lojiji laiṣe ọtá, tabi ti o sọ ohunkohun lù u laiba dè e,

23. Tabi okuta kan li o sọ, nipa eyiti enia le fi kú, ti kò ri i, ti o si sọ ọ lù u, ti on si kú, ti ki ṣe ọtá rẹ̀, ti kò si wá ibi rẹ̀:

24. Nigbana ni ki ijọ ki o ṣe idajọ lãrin ẹniti o pa enia ati agbẹsan ẹ̀jẹ na, gẹgẹ bi idajọ wọnyi:

25. Ki ijọ ki o si gbà ẹniti o pani li ọwọ́ agbẹsan ẹ̀jẹ, ki ijọ ki o si mú u pada lọ si ilu àbo rẹ̀, nibiti o ti sá si: ki o si ma gbé ibẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa, ti a fi oróro mimọ́ yàn.

Ka pipe ipin Num 35