Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 34:3-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Njẹ ki ìha gusù nyin ki o jẹ́ ati aginjù Sini lọ titi dé ẹba Edomu, ati opinlẹ gusù nyin ki o jẹ́ lati opin Okun Iyọ̀ si ìha ìla-õrùn:

4. Ki opinlẹ nyin ki o si yí lati gusù wá si ìgoke Akrabbimu, ki o si kọja lọ si Sini: ati ijadelọ rẹ̀ ki o jẹ́ ati gusù lọ si Kadeṣi-barnea, ki o si dé Hasari-addari, ki o si kọja si Asmoni:

5. Ki opinlẹ rẹ̀ ki o si yiká lati Asmoni lọ dé odò Egipti, okun ni yio si jẹ́ opin rẹ̀.

6. Ati opinlẹ ìha ìwọ-õrùn, ani okun nla ni yio jẹ́ opin fun nyin: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ìwọ-õrùn fun nyin.

7. Eyi ni yio si jẹ́ opinlẹ ìha ariwa fun nyin: lati okun nla lọ ki ẹnyin ki o fi ori sọ òke Hori:

8. Lati òke Hori lọ ki ẹnyin ki o fi ori sọ ati wọ̀ Hamati; ijadelọ opinlẹ na yio si jẹ́ Sedadi:

9. Opinlẹ rẹ yio si dé Sifroni, ati ijadelọ rẹ̀ yio dé Hasari-enani: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ariwa nyin.

10. Ki ẹnyin ki o si sàmi si opinlẹ nyin ni ìha ìla-õrùn lati Hasari-enani lọ dé Ṣefamu:

11. Ki opinlẹ na ki o si ti Ṣefamu sọkalẹ lọ si Ribla, ni ìha ìla-õrùn Aini; ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ, ki o si dé ìha okun Kinnereti ni ìha ìla-õrùn.

12. Ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ si Jordani, ijadelọ rẹ̀ yio jẹ Okun Iyọ̀: eyi ni yio jẹ́ ilẹ nyin gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀ yiká kiri.

13. Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi ni ilẹ na ti ẹnyin o fi keké gbà ni iní, ti OLUWA paṣẹ lati fi fun ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya nì:

14. Fun ẹ̀ya awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi ile baba wọn, ati ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi ile baba wọn ti gbà; àbọ ẹ̀ya Manasse si ti gbà, ipín wọn:

15. Ẹ̀ya mejẽji ati àbọ ẹ̀ya nì ti gbà ipín wọn ni ìha ihin Jordani leti Jeriko, ni ìha gabasi, ni ìha ìla-õrùn.

16. OLUWA si sọ fun Mose pe,

17. Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin ti yio pín ilẹ na fun nyin: Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni.

18. Ki ẹnyin ki o si mú olori kan ninu ẹ̀ya kọkan, lati pín ilẹ na ni iní.

19. Orukọ awọn ọkunrin na si ni wọnyi: ni ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne.

20. Ati ni ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, Ṣemueli ọmọ Ammihudu.

Ka pipe ipin Num 34