Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 34:16-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. OLUWA si sọ fun Mose pe,

17. Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin ti yio pín ilẹ na fun nyin: Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni.

18. Ki ẹnyin ki o si mú olori kan ninu ẹ̀ya kọkan, lati pín ilẹ na ni iní.

19. Orukọ awọn ọkunrin na si ni wọnyi: ni ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne.

20. Ati ni ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, Ṣemueli ọmọ Ammihudu.

21. Ni ẹ̀ya Benjamini, Elidadi ọmọ Kisloni.

22. Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Dani, Bukki ọmọ Jogli.

23. Olori awọn ọmọ Josefu: ni ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse, Hannieli ọmọ Efodu:

24. Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu, Kemueli ọmọ Ṣiftani.

25. Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Sebuluni, Elisafani ọmọ Parnaki.

26. Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari, Paltieli ọmọ Assani.

27. Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri, Ahihudu ọmọ Ṣelomi.

28. Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali, Pedaheli ọmọ Ammihudu.

Ka pipe ipin Num 34