Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 34:15-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ẹ̀ya mejẽji ati àbọ ẹ̀ya nì ti gbà ipín wọn ni ìha ihin Jordani leti Jeriko, ni ìha gabasi, ni ìha ìla-õrùn.

16. OLUWA si sọ fun Mose pe,

17. Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin ti yio pín ilẹ na fun nyin: Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni.

18. Ki ẹnyin ki o si mú olori kan ninu ẹ̀ya kọkan, lati pín ilẹ na ni iní.

19. Orukọ awọn ọkunrin na si ni wọnyi: ni ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne.

20. Ati ni ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, Ṣemueli ọmọ Ammihudu.

21. Ni ẹ̀ya Benjamini, Elidadi ọmọ Kisloni.

22. Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Dani, Bukki ọmọ Jogli.

Ka pipe ipin Num 34