Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 32:36-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Ati Beti-nimra, ati Beti-harani, ilu olodi, ati agbo fun agutan.

37. Awọn ọmọ Reubeni si kọ́ Heṣboni, ati Eleale, ati Kiriataimu.

38. Ati Nebo, ati Baali-meoni, (nwọn pàrọ orukọ wọn,) ati Sibma: nwọn si sọ ilu ti nwọn kọ́ li orukọ miran.

39. Awọn ọmọ Makiri ọmọ Manase si lọ si Gileadi, nwọn si gbà a, nwọn si lé awọn ọmọ Amori ti o wà ninu rẹ̀.

40. Mose si fi Gileadi fun Makiri ọmọ Manase; o si joko ninu rẹ̀.

41. Jairi ọmọ Manasse, si lọ, o si gbà awọn ilu wọn, o si sọ wọn ni Haffotu-jairi.

42. Noba si lọ, o si gbà Kenati, ati awọn ileto rẹ̀, o si sọ ọ ni Noba, nipa orukọ ara rẹ̀.

Ka pipe ipin Num 32