Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 32:32-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Awa o gòke lọ ni ihamọra niwaju OLUWA si ilẹ Kenaani, ki iní wa ni ìha ihin Jordani ki o le jẹ́ ti wa.

33. Mose si fi ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ati ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani fun wọn, ani fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse ọmọ Josefu, ilẹ na, pẹlu ilu rẹ̀ li àgbegbe rẹ̀, ani ilu ilẹ na yiká.

34. Awọn ọmọ Gadi si kọ́ Didoni, ati Atarotu, ati Aroeri;

35. Ati Atrotu-ṣofani, ati Jaseri, ati Jogbeha;

36. Ati Beti-nimra, ati Beti-harani, ilu olodi, ati agbo fun agutan.

37. Awọn ọmọ Reubeni si kọ́ Heṣboni, ati Eleale, ati Kiriataimu.

38. Ati Nebo, ati Baali-meoni, (nwọn pàrọ orukọ wọn,) ati Sibma: nwọn si sọ ilu ti nwọn kọ́ li orukọ miran.

39. Awọn ọmọ Makiri ọmọ Manase si lọ si Gileadi, nwọn si gbà a, nwọn si lé awọn ọmọ Amori ti o wà ninu rẹ̀.

40. Mose si fi Gileadi fun Makiri ọmọ Manase; o si joko ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Num 32