Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 32:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ní ọ̀pọlọpọ ohunọ̀sin: nwọn si ri ilẹ Jaseri, ati ilẹ Gileadi, si kiyesi i, ibẹ̀ na, ibi ohunọ̀sin ni;

2. Awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni si wá, nwọn si sọ fun Mose, ati fun Eleasari alufa ati fun awọn olori ijọ pe,

3. Atarotu, ati Diboni, ati Jaseri, ati Nimra, ati Heṣboni, ati Eleale, ati Ṣebamu, ati Nebo, ati Beoni.

4. Ilẹ na ti OLUWA ti kọlù niwaju ijọ Israeli, ilẹ ohunọ̀sin ni, awa iranṣẹ rẹ si ní ohunọ̀sin.

5. Nwọn si wipe, Bi awa ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, jẹ ki a fi ilẹ yi fun awọn iranṣẹ rẹ fun ilẹ-iní; ki o má si ṣe mú wa gòke Jordani lọ.

6. Mose si wi fun awọn ọmọ Gadi ati fun awọn ọmọ Reubeni pe, Awọn arakunrin nyin yio ha lọ si ogun, ki ẹnyin ki o si joko nihinyi?

7. Ẽṣe ti ẹnyin fi ntán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju ati rekọja lọ sinu ilẹ ti OLUWA fi fun wọn?

8. Bẹ̃li awọn baba nyin ṣe, nigbati mo rán wọn lati Kadeṣi-barnea lọ lati wò ilẹ na.

9. Nitoripe nigbati nwọn gòke lọ dé afonifoji Eṣkolu, ti nwọn si ri ilẹ na, nwọn tán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju, ki nwọn ki o má le lọ sinu ilẹ ti OLUWA ti fi fun wọn.

Ka pipe ipin Num 32