Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 31:50-54 Yorùbá Bibeli (YCE)

50. Nitorina li awa ṣe mú ọrẹ-ebọ wá fun OLUWA, ohunkohun ti olukuluku ri, ohun ọ̀ṣọ wurà, ẹ̀wọn, ati jufù, ati oruka-àmi, ati oruka-etí, ati ìlẹkẹ, lati fi ṣètutu fun ọkàn wa niwaju OLUWA.

51. Mose ati Eleasari alufa si gbà wurà na lọwọ wọn, ani gbogbo ohun-iṣẹ ọsọ́.

52. Ati gbogbo wurà ẹbọ igbesọsoke ti nwọn múwa fun OLUWA, lati ọdọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lati ọdọ awọn balogun ọrọrún, o jẹ́ ẹgba mẹjọ o le ẹdẹgbẹrin o le ãdọta ṣekeli.

53. (Nitoripe awọn ologun ti kó ẹrù, olukuluku fun ara rẹ̀.)

54. Mose ati Eleasari alufa si gbà wurà na lọwọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lọwọ awọn balogun ọrọrún nwọn si mú u wá sinu agọ́ ajọ, ni iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA.

Ka pipe ipin Num 31