Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 31:39-50 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. Kẹtẹkẹtẹ si jẹ́ ẹgba mẹdogun o le ẹdẹgbẹta; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ́ ọgọta o le ọkan.

40. Awọn enia si jẹ́ ẹgba mẹjọ; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ́ ọgbọ̀n o le meji.

41. Mose si fi idá ti ẹbọ igbesọsoke OLUWA fun Eleasari alufa, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

42. Ati ninu àbọ ti awọn ọmọ Israeli, ti Mose pín kuro ninu ti awọn ọkunrin ti o jagun na,

43. (Njẹ àbọ ti ijọ jẹ́ ẹgba mejidilãdọsan o le ẹdẹgbẹjọ agutan,

44. Ati ẹgba mejidilogun malu.

45. Ati ẹgba mẹdogun o le ẹdẹgbẹta kẹtẹkẹtẹ.

46. Ati ẹgba mẹjọ enia;)

47. Ani ninu àbọ ti awọn ọmọ Israeli, Mose mú ipín kan ninu ãdọta, ati ti enia ati ti ẹran, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

48. Ati awọn olori ti o wà lori ẹgbẹgbẹrun ogun na, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati awọn balogun ọrọrún, wá sọdọ Mose:

49. Nwọn si wi fun Mose pe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kà iye awọn ologun, ti mbẹ ni itọju wa, ọkunrin kan ninu wa kò si din.

50. Nitorina li awa ṣe mú ọrẹ-ebọ wá fun OLUWA, ohunkohun ti olukuluku ri, ohun ọ̀ṣọ wurà, ẹ̀wọn, ati jufù, ati oruka-àmi, ati oruka-etí, ati ìlẹkẹ, lati fi ṣètutu fun ọkàn wa niwaju OLUWA.

Ka pipe ipin Num 31