26. Kà iye ikogun ti a kó, ti enia ati ti ẹran, iwọ ati Eleasari alufa, ati awọn olori ile baba ijọ:
27. Ki o si pín ikogun na si ipa meji; lãrin awọn ologun, ti o jade lọ si ogun na, ati lãrin gbogbo ijọ.
28. Ki o si gbà ohun idá ti OLUWA lọwọ awọn ologun ti nwọn jade lọ si ogun na: ọkan ninu ẹdẹgbẹta, ninu awọn enia, ati ninu malu, ati ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran:
29. Gbà a ninu àbọ ti wọn, ki o si fi i fun Eleasari alufa, fun ẹbọ igbesọsoke OLUWA.
30. Ati ninu àbọ ti iṣe ti awọn ọmọ Israeli, ki iwọ ki o si gbà ipín kan ninu ãdọta, ninu enia, ninu malu, ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran, ninu onirũru ẹran, ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA.
31. Ati Mose ati Eleasari alufa si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.
32. Ati ikogun ti o kù ninu ohun-iní ti awọn ologun kó, o jẹ́ ọkẹ mẹrinlelọgbọ̀n o din ẹgbẹdọgbọ̀n agutan,
33. Ẹgba mẹrindilogoji malu,
34. Ọkẹ mẹta o le ẹgbẹrun kẹtẹkẹtẹ,
35. Ati enia ninu awọn obinrin ti kò mọ̀ ọkunrin nipa ibá dàpọ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun.
36. Ati àbọ ti iṣe ipín ti awọn ti o jade lọ si ogun, o jẹ́ ẹgba mejidilãdọsan o le ẹdẹgbẹjọ agutan ni iye:
37. Idá ti OLUWA ninu agutan wọnni jẹ́ ẹdẹgbẹrin o din mẹdọgbọ̀n.