Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 30:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ on o mu ẹjẹ́ rẹ̀ ti o jẹ́ ati ohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade, eyiti o fi dè ara rẹ̀ dasan: OLUWA yio si darijì i.

9. Ṣugbọn gbogbo ẹjẹ́ opó, ati ti obinrin ti a kọ̀silẹ, ti nwọn fi dè ara wọn, yio wà lọrùn rẹ̀.

10. Bi o ba si jẹjẹ́ ni ile ọkọ rẹ̀, tabi ti o si fi ibura dè ara rẹ̀ ni ìde,

11. Ti ọkọ rẹ̀ si gbọ́, ti o si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i, ti kò si kọ̀ fun u: njẹ gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ni yio duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro.

12. Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba sọ wọn dasan patapata li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ohunkohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade nipasẹ̀ ẹjẹ́ rẹ̀, tabi nipasẹ̀ ìde ọkàn rẹ̀, ki yio duro: ọkọ rẹ̀ ti sọ wọn dasan; OLUWA yio si darijì i.

13. Gbogbo ẹjẹ́ ati ibura ìde lati fi pọ́n ara loju, ọkọ rẹ̀ li o le mu u duro, o si le sọ ọ dasan.

14. Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i patapata lati ọjọ́ dé ọjọ́; njẹ o fi mu gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ duro, tabi gbogbo ìde rẹ̀ ti mbẹ lara rẹ̀; o mu wọn duro, nitoriti o pa ẹnu rẹ̀ mọ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́.

15. Ṣugbọn bi o ba sọ wọn dasan, lẹhin igbati o gbọ́; njẹ on ni yio rù ẹ̀ṣẹ obinrin na.

16. Wọnyi ni ìlana ti OLUWA palaṣẹ fun Mose, lãrin ọkunrin ati aya rẹ̀, lãrin baba ati ọmọbinrin rẹ̀, ti iṣe ewe ninu ile baba rẹ̀.

Ka pipe ipin Num 30