Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 3:41-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Ki iwọ ki o si gbà awọn ọmọ Lefi fun mi (Emi li OLUWA) ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli; ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi, ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli.

42. Mose si kà gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, bi OLUWA ti paṣẹ fun u.

43. Ati gbogbo awọn akọ́bi ọkunrin nipa iye orukọ, lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ ninu eyiti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkanla o le ọrinlugba o din meje.

44. OLUWA si sọ fun Mose pe,

45. Gbà awọn ọmọ Lefi ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi nipò ohun-ọ̀sin wọn; awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi; Emi li OLUWA.

46. Ati fun ìrapada awọn ọrinlugba din meje ti awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ti nwọn fi jù awọn ọmọ Lefi lọ,

47. Ani ki o gbà ṣekeli marun-marun li ori ẹni kọkan, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́ ni ki o gbà wọn; (ogun gera ni ṣekeli kan):

48. Ki o si fi ninu owo na, ani owo ìrapada ti o lé ninu wọn, fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Num 3