Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 3:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI si li awọn iran Aaroni ati Mose li ọjọ́ ti OLUWA bá Mose sọ̀rọ li òke Sinai.

2. Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Aaroni; Nadabu akọ́bi, ati Abihu, Eleasari, ati Itamari.

3. Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa ti a ta oróro si wọn li ori, ẹniti o yàsọtọ lati ma ṣe iranṣẹ ni ipò iṣẹ alufa.

4. Nadabu ati Abihu si kú niwaju OLUWA, nigbati nwọn rubọ iná àjeji niwaju OLUWA ni ijù Sinai, nwọn kò si lí ọmọ: ati Eleasari ati Itamari nṣe iṣẹ alufa niwaju Aaroni baba wọn.

5. OLUWA si sọ fun Mose pe,

6. Mú ẹ̀ya Lefi sunmọtosi, ki o si mú wọn wá siwaju Aaroni alufa, ki nwọn le ma ṣe iranṣẹ fun u.

7. Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ gbogbo ajọ niwaju agọ́ ajọ, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́.

Ka pipe ipin Num 3