Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 24:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI Balaamu ri pe o wù OLUWA lati bukún Israeli, on kò lọ mọ́ bi ìgba iṣaju, lati wá ìfaiya, ṣugbọn o doju rẹ̀ kọ aginjù.

2. Balaamu si gbé oju rẹ̀ soke o si ri Israeli dó gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; ẹmi Ọlọrun si wá sara rẹ̀.

3. O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ sí nwi:

4. Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o nri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ ṣí.

5. Jakobu, agọ́ rẹ wọnyi ti dara tó, ati ibugbé rẹ iwọ Israeli!

6. Bi afonifoji ni nwọn tẹ́ lọ bẹrẹ, bi ọgbà lẹba odònla, bi igi aloe ti OLUWA gbìn, ati bi igi kedari lẹba omi.

7. Omi o ṣàn jade lati inu agbè rẹ̀ wá, irú rẹ̀ yio si wà ninu omi pupọ̀, ọba rẹ̀ yio si ga jù Agagi lọ, ijọba rẹ̀ li a o si gbeleke.

Ka pipe ipin Num 24