Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 21:21-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, wipe,

22. Jẹ ki emi là ilẹ rẹ kọja lọ: awa ki yio yà sinu oko, tabi ọgba-àjara; awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li a o gbà, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ.

23. Sihoni kò si jẹ ki Israeli ki o là àgbegbe rẹ̀ kọja: ṣugbọn Sihoni kó gbogbo awọn enia rẹ̀ jọ, nwọn si jade tọ̀ Israeli lọ li aginjù, o si wá si Jahasi, o bá Israeli jà.

24. Israeli si fi oju idà kọlù u, o si gbà ilẹ rẹ̀ lati Arnoni lọ dé Jaboku, ani dé ti awọn ọmọ Ammoni; nitoripe ipinlẹ ti awọn ọmọ Ammoni lí agbara.

25. Israeli si gbà gbogbo ilunla wọnni: Israeli si joko ninu gbogbo ilunla ti awọn ọmọ Amori, ni Heṣboni, ati ni ilu rẹ̀ gbogbo.

26. Nitoripe Heṣboni ni ilunla Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ẹniti o ti bá ọba Moabu atijọ jà, ti o si gbà gbogbo ilẹ rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, titi dé Arnoni.

27. Nitorina awọn ti nkọrin owe a ma wipe, Wá si Heṣboni, jẹ ki a tẹ̀ ilunla Sihoni dó ki a si tun fi idi rẹ̀ mulẹ:

28. Nitoriti iná kan ti Heṣboni jade lọ, ọwọ́-iná kan lati ilunla Sihoni: o si run Ari ti Moabu, ati awọn oluwa ibi giga Arnoni.

29. Egbé ni fun iwọ, Moabu! Ẹ gbé, ẹnyin enia Kemoṣi: on ti fi awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bi isansa, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin bi igbekun, fun Sihoni ọba awọn ọmọ Amori.

30. Awa tafà si wọn; Heṣboni ṣegbé titi dé Diboni, awa si ti run wọn titi dé Nofa, ti o dé Medeba.

31. Bẹ̃li awọn ọmọ Israeli joko ni ilẹ awọn ọmọ Amori.

32. Mose si rán enia lọ ṣe amí Jaseri, nwọn si gbà ilu rẹ̀, nwọn si lé awọn ọmọ Amori ti o wà nibẹ̀.

33. Nwọn si yipada, nwọn si gòke lọ li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade tọ̀ wọn lọ, on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, si ogun ni Edrei.

34. OLUWA si wi fun Mose pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe mo ti fi on lé ọ lọwọ, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀; ki iwọ ki o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni.

35. Bẹ̃ni nwọn si kọlù u, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, titi kò fi kù ọkan silẹ fun u lãye: nwọn si gbà ile rẹ̀.

Ka pipe ipin Num 21