Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 20:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN ọmọ Israeli si wá, ani gbogbo ijọ, si aginjù Sini li oṣù kini: awọn enia na si joko ni Kadeṣi; Miriamu si kú nibẹ̀, a si sin i nibẹ̀.

2. Omi kò si sí fun ijọ: nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni.

3. Awọn enia si mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Awa iba kuku ti kú nigbati awọn arakunrin wa kú niwaju OLUWA!

4. Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú ijọ OLUWA wá si aginjù yi, ki awa ati ẹran wá ki o kú nibẹ̀?

5. Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke ti Egipti wá, lati mú wa wá si ibi buburu yi? ki iṣe ibi irugbìn, tabi ti ọpọtọ, tabi ti àjara, tabi ti pomegranate; bẹ̃ni kò sí omi lati mu.

6. Mose ati Aaroni si lọ kuro niwaju ijọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, nwọn si doju wọn bolẹ: ogo OLUWA si hàn si wọn.

Ka pipe ipin Num 20