Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 17:8-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. O si ṣe, ni ijọ́ keji ti Mose wọ̀ inu agọ́ ẹrí lọ; si kiyesi i, ọpá Aaroni fun ile Lefi rudi, o si tú, o si tanna, o si so eso almondi.

9. Mose si kó gbogbo ọpá na lati iwaju OLUWA jade tọ̀ gbogbo awọn ọmọ Israeli wá: nwọn si wò, olukuluku si mú ọpá tirẹ̀.

10. OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú ọpá Aaroni pada wa siwaju ẹrí, lati fi pamọ́ fun àmi fun awọn ọlọ̀tẹ nì; ki iwọ ki o si gbà kikùn wọn kuro lọdọ mi patapata ki nwọn ki o má ba kú.

11. Mose si ṣe bẹ̃: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun u, bẹ̃li o ṣe.

12. Awọn ọmọ Israeli si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, awa kú, awa gbé, gbogbo wa gbé.

13. Ẹnikẹni ti o ba sunmọ agọ́ OLUWA yio kú: awa o ha fi kikú run bi?

Ka pipe ipin Num 17