Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 17:2-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si gbà ọpá kọkan lọwọ wọn, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, lọwọ gbogbo awọn olori wọn gẹgẹ bi ile awọn baba wọn ọpá mejila: ki o si kọ́ orukọ olukuluku si ara ọpá rẹ̀.

3. Ki o si kọ orukọ Aaroni sara ọpá Lefi: nitoripe ọpá kan yio jẹ́ fun ori ile awọn baba wọn.

4. Ki o si fi wọn lelẹ ninu agọ́ ajọ, niwaju ẹrí, nibiti emi o gbé pade nyin.

5. Yio si ṣe, ọpá ẹniti emi o yàn yio ruwe: emi o si da kikùn awọn ọmọ Israeli duro kuro lọdọ mi, ti nwọn nkùn si nyin.

6. Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, gbogbo awọn olori wọn si fun u li ọpá, ọpá kan fun olori kan, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, ani ọpá mejila: ọpá Aaroni si wà ninu ọpá wọn.

7. Mose si fi ọpá wọnni lelẹ niwaju OLUWA ninu agọ́ ẹrí.

8. O si ṣe, ni ijọ́ keji ti Mose wọ̀ inu agọ́ ẹrí lọ; si kiyesi i, ọpá Aaroni fun ile Lefi rudi, o si tú, o si tanna, o si so eso almondi.

Ka pipe ipin Num 17