Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 16:46-50 Yorùbá Bibeli (YCE)

46. Mose si wi fun Aaroni pe, Mú awo-turari kan, ki o si fi iná sinu rẹ̀ lati ori pẹpẹ nì wá, ki o si fi turari lé ori rẹ̀, ki o si yára lọ sọdọ ijọ, ki o si ṣètutu fun wọn: nitoriti ibinu jade lati ọdọ OLUWA lọ; iyọnu ti bẹ̀rẹ na.

47. Aaroni si mú awo-turari bi Mose ti fi aṣẹ fun u, o si sure lọ sãrin ijọ; si kiyesi i, iyọnu ti bẹ̀rẹ na lãrin awọn enia: o si fi turari sinu rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn enia na.

48. O si duro li agbedemeji okú ati alãye; iyọnu na si duro.

49. Awọn ti o kú ninu iyọnu na si jẹ́ ẹgba meje o le ẹ̃dẹgbẹrin, laìka awọn ti o kú niti ọ̀ran Kora.

50. Aaroni si pada tọ̀ Mose lọ si ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: iyọnu na si duro.

Ka pipe ipin Num 16