Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 16:33-49 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Awọn, ati ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, sọkalẹ lọ lãye si ipò-okú, ilẹ si pa ẹnu dé mọ́ wọn, nwọn si run kuro ninu ijọ.

34. Gbogbo enia Israeli ti o yi wọn ká si salọ nitori igbe wọn: nitoriti nwọn wipe, Ki ilẹ ki o má ba gbe wa mì pẹlu.

35. Iná si jade wá lati ọdọ OLUWA, o si run awọn ãdọtalerugba ọkunrin nì ti nwọn mú turari wá.

36. OLUWA si sọ fun Mose pe,

37. Sọ fun Eleasari ọmọ Aaroni alufa, pe ki o mú awo-turari wọnni kuro ninu ijóna, ki iwọ ki o si tu iná na ká sọhún; nitoripe nwọn jẹ́ mimọ́.

38. Awo-turari ti awọn ẹlẹṣẹ wọnyi si ọkàn ara wọn, ni ki nwọn ki o fi ṣe awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: nitoriti nwọn mú wọn wá siwaju OLUWA, nitorina ni nwọn ṣe jẹ́ mimọ́: nwọn o si ma ṣe àmi fun awọn ọmọ Israeli.

39. Eleasari alufa si mú awo-turari idẹ wọnni, eyiti awọn ẹniti o jóna fi mú ẹbọ wá; a si rọ wọn li awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ:

40. Lati ma ṣe ohun iranti fun awọn ọmọ Israeli, ki alejò kan, ti ki iṣe irú-ọmọ Aaroni, ki o máṣe sunmọtosi lati mú turari wá siwaju OLUWA; ki o má ba dabi Kora, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀: bi OLUWA ti wi fun u lati ọwọ́ Mose wá.

41. Ṣugbọn ni ijọ́ keji gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli nkùn si Mose ati si Aaroni, wipe, Ẹnyin pa awọn enia OLUWA.

42. O si ṣe, nigbati ijọ pejọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, ti nwọn si wò ìha agọ́ ajọ: si kiyesi i, awọsanma bò o, ogo OLUWA si farahàn.

43. Mose ati Aaroni si wá siwaju agọ́ ajọ.

44. OLUWA si sọ fun Mose pe,

45. Ẹ lọ kuro lãrin ijọ yi, ki emi ki o run wọn ni iṣẹju kan. Nwọn si doju wọn bolẹ.

46. Mose si wi fun Aaroni pe, Mú awo-turari kan, ki o si fi iná sinu rẹ̀ lati ori pẹpẹ nì wá, ki o si fi turari lé ori rẹ̀, ki o si yára lọ sọdọ ijọ, ki o si ṣètutu fun wọn: nitoriti ibinu jade lati ọdọ OLUWA lọ; iyọnu ti bẹ̀rẹ na.

47. Aaroni si mú awo-turari bi Mose ti fi aṣẹ fun u, o si sure lọ sãrin ijọ; si kiyesi i, iyọnu ti bẹ̀rẹ na lãrin awọn enia: o si fi turari sinu rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn enia na.

48. O si duro li agbedemeji okú ati alãye; iyọnu na si duro.

49. Awọn ti o kú ninu iyọnu na si jẹ́ ẹgba meje o le ẹ̃dẹgbẹrin, laìka awọn ti o kú niti ọ̀ran Kora.

Ka pipe ipin Num 16