Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 16:27-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Bẹ̃ni nwọn si gòke lọ kuro nibi agọ́ Kora, Datani ati Abiramu, ni ìha gbogbo: Datani ati Abiramu si jade, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ wọn, ati awọn aya wọn, ati awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn wẹ́wẹ.

28. Mose si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe OLUWA li o rán mi lati ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi; ati pe emi kò ṣe wọn lati inu ara mi wá.

29. Bi awọn ọkunrin wọnyi ba kú bi gbogbo enia ti ikú, tabi bi a ba si bẹ̀ wọn wò bi ãti ibẹ̀ gbogbo enia wò; njẹ OLUWA ki o rán mi.

30. Ṣugbọn bi OLUWA ba ṣe ohun titun, ti ilẹ ba si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, pẹlu ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, ti nwọn si sọkalẹ lọ si ipò-okú lãye; nigbana ẹnyin o mọ̀ pe awọn ọkunrin wọnyi ti gàn OLUWA.

31. O si ṣe, bi o ti pari gbogbo ọ̀rọ wọnyi ni sisọ, ni ilẹ là pẹrẹ nisalẹ wọn:

32. Ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si gbe wọn mì, ati awọn ara ile wọn, ati gbogbo awọn enia ti iṣe ti Kora, ati gbogbo ẹrù wọn.

33. Awọn, ati ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, sọkalẹ lọ lãye si ipò-okú, ilẹ si pa ẹnu dé mọ́ wọn, nwọn si run kuro ninu ijọ.

34. Gbogbo enia Israeli ti o yi wọn ká si salọ nitori igbe wọn: nitoriti nwọn wipe, Ki ilẹ ki o má ba gbe wa mì pẹlu.

35. Iná si jade wá lati ọdọ OLUWA, o si run awọn ãdọtalerugba ọkunrin nì ti nwọn mú turari wá.

36. OLUWA si sọ fun Mose pe,

37. Sọ fun Eleasari ọmọ Aaroni alufa, pe ki o mú awo-turari wọnni kuro ninu ijóna, ki iwọ ki o si tu iná na ká sọhún; nitoripe nwọn jẹ́ mimọ́.

38. Awo-turari ti awọn ẹlẹṣẹ wọnyi si ọkàn ara wọn, ni ki nwọn ki o fi ṣe awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: nitoriti nwọn mú wọn wá siwaju OLUWA, nitorina ni nwọn ṣe jẹ́ mimọ́: nwọn o si ma ṣe àmi fun awọn ọmọ Israeli.

39. Eleasari alufa si mú awo-turari idẹ wọnni, eyiti awọn ẹniti o jóna fi mú ẹbọ wá; a si rọ wọn li awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ:

40. Lati ma ṣe ohun iranti fun awọn ọmọ Israeli, ki alejò kan, ti ki iṣe irú-ọmọ Aaroni, ki o máṣe sunmọtosi lati mú turari wá siwaju OLUWA; ki o má ba dabi Kora, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀: bi OLUWA ti wi fun u lati ọwọ́ Mose wá.

41. Ṣugbọn ni ijọ́ keji gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli nkùn si Mose ati si Aaroni, wipe, Ẹnyin pa awọn enia OLUWA.

42. O si ṣe, nigbati ijọ pejọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, ti nwọn si wò ìha agọ́ ajọ: si kiyesi i, awọsanma bò o, ogo OLUWA si farahàn.

Ka pipe ipin Num 16