Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 15:23-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ani gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun nyin lati ọwọ́ Mose wá, lati ọjọ́ na ti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati lati isisiyi lọ, ni iran-iran nyin;

24. Yio si ṣe, bi a ba fi aimọ̀ ṣe ohun kan ti ijọ kò mọ̀, ki gbogbo ijọ ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá fun ẹbọ sisun, fun õrùn didùn si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀, gẹgẹ bi ìlana na, ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

25. Ki alufa ki o si ṣètutu fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, a o si darijì wọn; nitoripe aimọ̀ ni, nwọn si ti mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn niwaju OLUWA, nitori aimọ̀ wọn:

26. A o si darijì gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ati alejò ti iṣe atipo lọdọ wọn; nitoripe gbogbo enia wà li aimọ̀.

27. Bi ọkàn kan ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀, nigbana ni ki o mú abo-ewurẹ ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

28. Ki alufa ki o ṣètutu fun ọkàn na ti o ṣẹ̀, nigbati o ba ṣẹ̀ li aimọ̀ niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun u; a o si darijì i.

29. Ofin kan ni ki ẹnyin ki o ní fun ẹniti o ṣẹ̀ ni aimọ̀, ati fun ẹniti a bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn.

30. Ṣugbọn ọkàn na ti o ba fi ikugbu ṣe ohun kan, iba ṣe ibilẹ tabi alejò, o sọ̀rọbuburu si OLUWA; ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

31. Nitoriti o gàn ọ̀rọ OLUWA, o si ru ofin rẹ̀; ọkàn na li a o ke kuro patapata, ẹ̀ṣẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀.

32. Nigbati awọn ọmọ Israeli wà li aginjù, nwọn ri ọkunrin kan ti nṣẹ́ igi li ọjọ́-isimi.

33. Awọn ti o ri i ti nṣẹ́ igi mú u tọ̀ Mose ati Aaroni wá, ati gbogbo ijọ.

34. Nwọn si há a mọ́ ile-ìde, nitoriti a kò ti isọ bi a o ti ṣe e.

35. OLUWA si sọ fun Mose pe, Pipa li a o pa ọkunrin na: gbogbo ijọ ni yio sọ ọ li okuta pa lẹhin ibudó.

36. Gbogbo ijọ si mú u wá sẹhin ibudó, nwọn si sọ ọ li okuta, on si kú; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

37. OLUWA si sọ fun Mose pe,

38. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si fi aṣẹ fun wọn ki nwọn ki o ṣe wajawaja si eti aṣọ wọn ni iran-iran wọn, ati ki nwọn ki o si fi ọjábulẹ alaró si wajawaja eti aṣọ na:

39. Yio si ma ṣe bi wajawaja fun nyin, ki ẹnyin ki o le ma wò o, ki ẹ si ma ranti gbogbo ofin OLUWA, ki ẹ si ma ṣe wọn: ki ẹnyin ki o má si ṣe tẹle ìro ọkàn nyin ati oju ara nyin, ti ẹnyin ti ima ṣe àgbere tọ̀ lẹhin:

40. Ki ẹnyin ki o le ma ranti, ki ẹ si ma ṣe ofin mi gbogbo, ki ẹnyin ki o le jẹ́ mimọ́ si Ọlọrun nyin.

Ka pipe ipin Num 15