Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 15:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ibujoko nyin, ti mo fi fun nyin,

3. Ti ẹnyin o ba si ṣe ẹbọ iná si OLUWA, ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá, tabi ninu ajọ nyin lati ṣe õrùn didùn si OLUWA ninu agbo-ẹran, tabi ọwọ́-ẹran:

4. Nigbana ni ki ẹniti nru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ na si OLUWA ki o mú ẹbọ ohunjijẹ wá, idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro pò:

5. Ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ ohunmimu ni ki iwọ ki o pèse pẹlu ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, fun ọdọ-agutan kan.

6. Tabi fun àgbo kan, ki iwọ ki o pèse ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun pẹlu idamẹta òṣuwọn hini oróro:

7. Ati fun ẹbọ ohunmimu, ki iwọ ki o mú idamẹta òṣuwọn hini ọti-waini wá, fun õrùn didùn si OLUWA.

8. Bi iwọ ba si pèse ẹgbọrọ akọmalu kan fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ alafia si OLUWA:

9. Nigbana ni ki o mu wá pẹlu ẹgbọrọ akọmalu na, ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun ti a fi àbọ òsuwọn hini oróro pò.

10. Ki iwọ ki o si múwa fun ẹbọ ohunmimu àbọ òṣuwọn hini ọti-waini, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.

Ka pipe ipin Num 15