Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 14:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nwọn si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ na dara gidigidi.

8. Bi OLUWA ba fẹ́ wa, njẹ yio mú wa wọ̀ inu ilẹ na yi, yio si fi i fun wa; ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.

9. Ṣugbọn ẹ máṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru awọn enia ilẹ na; nitoripe onjẹ wa ni nwọn; àbo wọn ti fi wọn silẹ, OLUWA si wà pẹlu wa: ẹ máṣe bẹ̀ru wọn.

10. Gbogbo ijọ si wipe ki a sọ wọn li okuta. Ṣugbọn ogo OLUWA hàn ninu agọ́ ajọ niwaju gbogbo awọn ọmọ Israeli.

11. OLUWA si wi fun Mose pe, Awọn enia yi yio ti kẹgàn mi pẹ tó? yio si ti pẹ tó ti nwọn o ṣe alaigbà mi gbọ́, ni gbogbo iṣẹ-àmi ti mo ṣe lãrin wọn?

12. Emi o fi ajakalẹ-àrun kọlù wọn, emi o si gbà ogún wọn lọwọ wọn, emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla, ati alagbara jù wọn lọ.

13. Mose si wi fun OLUWA pe, Ṣugbọn awọn ara Egipti yio gbọ́; nitoripe nipa agbara rẹ ni iwọ fi mú awọn enia yi jade lati inu wọn wá;

14. Nwọn o si wi fun awọn ara ilẹ yi: nwọn sá ti gbọ́ pe iwọ OLUWA mbẹ lãrin awọn enia yi, nitoripe a ri iwọ OLUWA li ojukoju, ati pe awọsanma rẹ duro lori wọn, ati pe iwọ li o ṣaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma nigba ọsán, ati ninu ọwọ̀n iná li oru.

15. Njẹ bi iwọ ba pa gbogbo awọn enia yi bi ẹnikan, nigbana li awọn orilẹ-ède ti o ti gbọ́ okikí rẹ yio wipe,

16. Nitoriti OLUWA kò le mú awọn enia yi dé ilẹ ti o ti fi bura fun wọn, nitorina li o ṣe pa wọn li aginjù.

17. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki agbara OLUWA ki o tobi, gẹgẹ bi iwọ ti sọ rí pe,

18. Olupamọra ati ẹniti o pọ̀ li ãnu li OLUWA, ti ndari ẹ̀ṣẹ ati irekọja jì, ati bi o ti wù ki o ri, ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijìya; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, titi dé iran kẹta ati ẹkẹrin.

19. Emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ awọn enia yi jì, gẹgẹ bi titobi ãnu rẹ, ati bi iwọ ti darijì awọn enia yi, lati Egipti titi di isisiyi.

20. OLUWA si wipe, Emi ti darijì gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ:

Ka pipe ipin Num 14