Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 14:14-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nwọn o si wi fun awọn ara ilẹ yi: nwọn sá ti gbọ́ pe iwọ OLUWA mbẹ lãrin awọn enia yi, nitoripe a ri iwọ OLUWA li ojukoju, ati pe awọsanma rẹ duro lori wọn, ati pe iwọ li o ṣaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma nigba ọsán, ati ninu ọwọ̀n iná li oru.

15. Njẹ bi iwọ ba pa gbogbo awọn enia yi bi ẹnikan, nigbana li awọn orilẹ-ède ti o ti gbọ́ okikí rẹ yio wipe,

16. Nitoriti OLUWA kò le mú awọn enia yi dé ilẹ ti o ti fi bura fun wọn, nitorina li o ṣe pa wọn li aginjù.

17. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki agbara OLUWA ki o tobi, gẹgẹ bi iwọ ti sọ rí pe,

18. Olupamọra ati ẹniti o pọ̀ li ãnu li OLUWA, ti ndari ẹ̀ṣẹ ati irekọja jì, ati bi o ti wù ki o ri, ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijìya; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, titi dé iran kẹta ati ẹkẹrin.

19. Emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ awọn enia yi jì, gẹgẹ bi titobi ãnu rẹ, ati bi iwọ ti darijì awọn enia yi, lati Egipti titi di isisiyi.

20. OLUWA si wipe, Emi ti darijì gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ:

21. Ṣugbọn nitõtọ, bi mo ti wà, gbogbo aiye yio si kún fun ogo OLUWA;

22. Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi;

23. Nitõtọ nwọn ki yio ri ilẹ na ti mo ti fi bura fun awọn baba wọn, bẹ̃ni ọkan ninu awọn ti o gàn mi ki yio ri i:

Ka pipe ipin Num 14